Native Bible

Acts 23:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”

Acts 23:15 in English

Acts 23:15 · Berean Standard Bible

Now then, you and the Sanhedrin petition the commander to bring him down to you on the pretext of examining his case more carefully. We are ready to kill him on the way.”

Context

13Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ. 14Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu. 15Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.” 16Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu. 17Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.