Native Bible

Acts 22:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Alábojútó-ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.” Paulu wí pé, “Ṣùgbọ́n a bí mi sínú rẹ̀ ni.”

Acts 22:28 in English

Acts 22:28 · Berean Standard Bible

“I paid a high price for my citizenship,” said the commander. “But I was born a citizen,” Paul replied.

Context

26Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Romu ní i ṣe?” 27Alábojútó-ogun sì dé, ó sì bí Paulu pé, “Sọ fún mi, ará Romu ni ìwọ jẹ́ bí?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” 28Alábojútó-ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.” Paulu wí pé, “Ṣùgbọ́n a bí mi sínú rẹ̀ ni.” 29Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fàsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Olórí ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Romu ní Paulu i ṣe, àti nítorí ó tí dè é. 30Ní ọjọ́ kejì, nítorí tí olórí ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Paulu sùn sí, ó tú u sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Paulu sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró níwájú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.