Ìṣe àwọn Aposteli 2:20
Acts 2:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ó sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.
Acts 2:20 in English
Acts 2:20 · Berean Standard Bible
The sun will be turned to darkness, and the moon to blood, before the coming of the great and glorious Day of the Lord.
Context
18àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi obìnrin,
ni Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mi jáde ni ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì:
wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀. 19Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,
àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;
ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín; 20A ó sọ oòrùn di òkùnkùn,
àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,
kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé. 21Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe
orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’ 22“Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.