Ìṣe àwọn Aposteli 2:22
Acts 2:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú.
Acts 2:22 in English
Acts 2:22 · Berean Standard Bible
Men of Israel, listen to this message: Jesus of Nazareth was a man certified by God to you by miracles, wonders, and signs, which God did among you through Him, as you yourselves know.
Context
20A ó sọ oòrùn di òkùnkùn,
àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,
kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé. 21Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe
orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’ 22“Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú. 23Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, tí a sì pa á pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú, a kàn mọ́ àgbélébùú. 24Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú, nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.