Native Bible

Acts 15:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fàsẹ́yìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.

Acts 15:20 in English

Acts 15:20 · Berean Standard Bible

Instead, we should write and tell them to abstain from food polluted by idols, from sexual immorality, from the meat of strangled animals, and from blood.

Context

18ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá. 19“Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu. 20Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fàsẹ́yìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀. 21Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.” 22Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.