Ìṣe àwọn Aposteli 15:19
Acts 15:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.
Acts 15:19 in English
Acts 15:19 · Berean Standard Bible
It is my judgment, therefore, that we should not cause trouble for the Gentiles who are turning to God.
Context
17Kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,
àti gbogbo àwọn kèfèrí, lára ẹni tí a ń pe orúkọ mi,’
ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, 18ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá. 19“Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu. 20Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fàsẹ́yìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀. 21Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.