Ìṣe àwọn Aposteli 15:14
Acts 15:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.
Acts 15:14 in English
Acts 15:14 · Berean Standard Bible
Simon * has told us how God first visited the Gentiles to take from them a people to be His own.
Context
12Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà. 13Lẹ́yìn tí wọn sì dákẹ́, Jakọbu dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi, 14Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀. 15Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: 16“ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,
èmi ó sì tún àgọ́ Dafidi pa tí ó ti wó lulẹ̀:
èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,
èmi ó sì gbé e ró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.