Native Bible

Acts 13:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù,

Acts 13:18 in English

Acts 13:18 · Berean Standard Bible

He endured their conduct for about forty years in the wilderness.

Context

16Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi! 17Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀, 18ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù, 19nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní. 20Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta lé ní irinwó (450) ọdún. “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.