Native Bible

Acts 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.

Acts 10:16 in English

Acts 10:16 · Berean Standard Bible

This happened three times, and all at once the sheet was taken back up into heaven.

Context

14Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “Rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.” 15Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.” 16Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run. 17Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 18Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.