Native Bible

Acts 1:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa.

Acts 1:21 in English

Acts 1:21 · Berean Standard Bible

Therefore it is necessary to choose one of the men who have accompanied us the whole time the Lord Jesus went in and out among us,

Context

19Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.) 20Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé, “ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’ àti, “ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’ 21Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa. 22Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.” 23Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.