2 Tẹsalonika 3:5
2 Thessalonians 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.
2 Thessalonians 3:5 in English
2 Thessalonians 3:5 · Berean Standard Bible
May the Lord direct your hearts into God’s love and Christ’s perseverance.
Context
3Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. 4Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. 5Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi. 6Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. 7Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.