2 Tẹsalonika 3:7
2 Thessalonians 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.
2 Thessalonians 3:7 in English
2 Thessalonians 3:7 · Berean Standard Bible
For you yourselves know how you ought to imitate us, because we were not undisciplined among you,
Context
5Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi. 6Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. 7Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín. 8Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. 9Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.