2 Samuẹli 7:3
2 Samuel 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
2 Samuel 7:3 in English
2 Samuel 7:3 · Berean Standard Bible
And Nathan replied to the king, “Go and do all that is in your heart, for the LORD is with you.”
Context
1Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. 2Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó, èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.” 3Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” 4Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé, 5“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.