2 Samuẹli 7:1
2 Samuel 7:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.
2 Samuel 7:1 in English
2 Samuel 7:1 · Berean Standard Bible
After the king had settled into his palace and the LORD had given him rest from all his enemies around him,
Context
1Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. 2Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó, èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.” 3Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.