Native Bible

2 Samuel 7:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.

2 Samuel 7:5 in English

2 Samuel 7:5 · Berean Standard Bible

“Go and tell My servant David that this is what the LORD says: Are you the one to build for Me a house to dwell in?

Context

3Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” 4Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé, 5“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. 6Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi. 7Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.