Native Bible

2 Samuel 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà.

2 Samuel 6:4 in English

2 Samuel 6:4 · Berean Standard Bible

bringing with it the ark of God.* And Ahio was walking in front of the ark.

Context

2Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù. 3Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà. 4Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà. 5Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali. 6Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.