2 Samuẹli 5:19
2 Samuel 5:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.”
2 Samuel 5:19 in English
2 Samuel 5:19 · Berean Standard Bible
So David inquired of the LORD, “Should I go up against the Philistines? Will You deliver them into my hand?” “Go,” replied the LORD, “for I will surely deliver the Philistines into your hand.”
Context
17Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi. 18Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Refaimu. 19Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?”
Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.” 20Dafidi sì dé Baali-Perasimu, Dafidi sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọ̀tá mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baali-Perasimu. 21Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.