2 Samuẹli 5:17
2 Samuel 5:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi.
2 Samuel 5:17 in English
2 Samuel 5:17 · Berean Standard Bible
When the Philistines heard that David had been anointed king over Israel, they all went in search of him; but David learned of this and went down to the stronghold.
Context
15Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia. 16Àti Eliṣama, àti Eliada, àti Elifeleti. 17Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi. 18Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Refaimu. 19Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?”
Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.