Native Bible

2 Samuel 24:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Arauna sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀, Arauna sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀.

2 Samuel 24:20 in English

2 Samuel 24:20 · Berean Standard Bible

When Araunah looked out and saw the king and his servants coming toward him, he went out and bowed facedown before the king.

Context

18Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” 19Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, Dafidi sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á ní àṣẹ. 20Arauna sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀, Arauna sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀. 21Arauna sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?” Dafidi sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa, kí ààrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.” 22Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rú ẹbọ, wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.