2 Samuẹli 24:18
2 Samuel 24:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.”
2 Samuel 24:18 in English
2 Samuel 24:18 · Berean Standard Bible
And that day Gad came to David and said to him, “Go up and build an altar to the LORD on the threshing floor of Araunah the Jebusite.”
Context
16Nígbà tí angẹli náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jerusalẹmu láti pa á run, Olúwa sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún angẹli tí ń pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyí!” Angẹli Olúwa náà sì wà níbi ìpakà Arauna ará Jebusi. 17Dafidi sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.” 18Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” 19Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, Dafidi sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á ní àṣẹ. 20Arauna sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀, Arauna sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.