2 Samuẹli 24:17
2 Samuel 24:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”
2 Samuel 24:17 in English
2 Samuel 24:17 · Berean Standard Bible
When David saw the angel striking down the people, he said to the LORD, “Surely I, the shepherd,* have sinned and acted wickedly. But these sheep, what have they done? Please, let Your hand fall upon me and my father’s house.”
Context
15Olúwa sì rán ààrùn ìparun sí Israẹli láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá, ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dani títí fi dé Beerṣeba. 16Nígbà tí angẹli náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jerusalẹmu láti pa á run, Olúwa sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún angẹli tí ń pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyí!” Angẹli Olúwa náà sì wà níbi ìpakà Arauna ará Jebusi. 17Dafidi sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.” 18Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” 19Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, Dafidi sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á ní àṣẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.