Native Bible

2 Samuel 24:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé,

2 Samuel 24:11 in English

2 Samuel 24:11 · Berean Standard Bible

When David got up in the morning, a revelation from the LORD had come to Gad the prophet, David’s seer:

Context

9Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́. Ó sì jẹ́ ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà, àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ènìyàn. 10Àyà Dafidi sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dafidi sì wí fún Olúwa pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe, ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!” 11Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé, 12“Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ” 13Gadi sì tọ Dafidi wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí ààrùn ìparun ọjọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Rò ó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.