Native Bible

2 Samuel 24:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gadi sì tọ Dafidi wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí ààrùn ìparun ọjọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Rò ó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

2 Samuel 24:13 in English

2 Samuel 24:13 · Berean Standard Bible

So Gad went and said to David, “Do you choose to endure three * years of famine in your land, three months of fleeing the pursuit of your enemies, or three days of plague upon your land? Now then, think it over and decide how I should reply to Him who sent me.”

Context

11Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé, 12“Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ” 13Gadi sì tọ Dafidi wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí ààrùn ìparun ọjọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Rò ó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.” 14Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé Olúwa ní ọwọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn ní ọwọ́.” 15Olúwa sì rán ààrùn ìparun sí Israẹli láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá, ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dani títí fi dé Beerṣeba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.