2 Samuẹli 21:19
2 Samuel 21:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ.
2 Samuel 21:19 in English
2 Samuel 21:19 · Berean Standard Bible
Once again there was a battle with the Philistines at Gob, and Elhanan son of Jair * the Bethlehemite killed the brother of Goliath * the Gittite, the shaft of whose spear was like a weaver’s beam.
Context
17Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.” 18Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu, nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa. 19Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ. 20Ìjà kan sì tún wà ní Gati, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní Rafa. 21Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.