Native Bible

2 Samuel 21:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.”

2 Samuel 21:17 in English

2 Samuel 21:17 · Berean Standard Bible

But Abishai son of Zeruiah came to his aid, struck the Philistine, and killed him. Then David’s men swore to him, “You must never again go out with us to battle, so that the lamp of Israel may not be extinguished.”

Context

15Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà, ó sì rẹ Dafidi. 16Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi. 17Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.” 18Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu, nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa. 19Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.