Native Bible

2 Samuel 19:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah tí ẹ dàbí ọ̀tá fún mi lónìí? A ha lè pa ènìyàn kan lónìí ní Israẹli? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Israẹli.”

2 Samuel 19:22 in English

2 Samuel 19:22 · Berean Standard Bible

And David replied, “Sons of Zeruiah, what have I to do with you, that you should be my adversaries today? Should any man be put to death in Israel today? Am I not indeed aware that today I am king over Israel?”

Context

20Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wò ó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Josẹfu tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé olúwa mi ọba.” 21Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah dáhùn ó sì wí pé, “Kò ha tọ́ kí a pa Ṣimei nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró Olúwa.” 22Dafidi sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah tí ẹ dàbí ọ̀tá fún mi lónìí? A ha lè pa ènìyàn kan lónìí ní Israẹli? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Israẹli.” 23Ọba sì wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ kì yóò kú!” Ọba sì búra fún un. 24Mefiboṣeti ọmọ Saulu sì sọ̀kalẹ̀ láti wá pàdé ọba, kò wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, kò sí tọ́ irùngbọ̀n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti jáde títí ó fi di ọjọ́ tí ó fi padà ní àlàáfíà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.