2 Samuẹli 19:20
2 Samuel 19:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wò ó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Josẹfu tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé olúwa mi ọba.”
2 Samuel 19:20 in English
2 Samuel 19:20 · Berean Standard Bible
For your servant knows that I have sinned, so here I am today as the first of all the house of Joseph to come down to meet my lord the king.”
Context
18Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀.
Ṣimei ọmọ Gera wólẹ̀. Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jordani. 19Ó sì wí fún ọba pé, “Kí olúwa mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí olúwa mi ọba jáde ní Jerusalẹmu, kí ọba má sì fi sí inú. 20Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wò ó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Josẹfu tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé olúwa mi ọba.” 21Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah dáhùn ó sì wí pé, “Kò ha tọ́ kí a pa Ṣimei nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró Olúwa.” 22Dafidi sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah tí ẹ dàbí ọ̀tá fún mi lónìí? A ha lè pa ènìyàn kan lónìí ní Israẹli? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Israẹli.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.