2 Samuẹli 18:16
2 Samuel 18:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Joabu sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Israẹli, nítorí Joabu ti pe àwọn ènìyàn náà padà.
2 Samuel 18:16 in English
2 Samuel 18:16 · Berean Standard Bible
Then Joab blew the ram’s horn, and the troops broke off their pursuit of Israel because Joab had restrained them.
Context
14Joabu sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Absalomu ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láààyè ní agbede-méjì igi óákù náà. 15Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Joabu sì yí Absalomu ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á. 16Joabu sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Israẹli, nítorí Joabu ti pe àwọn ènìyàn náà padà. 17Wọ́n sì gbé Absalomu, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Israẹli sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀. 18Absalomu ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ́n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì Ọba: nítorí tí ó wí pé, “Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí,” òun sì pe ọ̀wọ́n náà nípa orúkọ rẹ̀, a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Absalomu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.