Native Bible

2 Samuel 17:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Absalomu sì gòkè odò Jordani, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli pẹ̀lú rẹ̀.

2 Samuel 17:24 in English

2 Samuel 17:24 · Berean Standard Bible

Then David went to Mahanaim, and Absalom crossed the Jordan with all the men of Israel.

Context

22Dafidi sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jordani: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jordani. 23Nígbà tí Ahitofeli sì rí i pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárì, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀. Absalomu gbógun ti Dafidi. 24Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Absalomu sì gòkè odò Jordani, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli pẹ̀lú rẹ̀. 25Absalomu sì fi Amasa ṣe olórí ogun ní ipò Joabu: Amasa ẹni tí í ṣe ọmọ ẹnìkan, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Itira, ará Israẹli, tí ó wọlé tọ Abigaili ọmọbìnrin Nahaṣi, arábìnrin Seruiah, ìyá Joabu. 26Israẹli àti Absalomu sì dó ní ilẹ̀ Gileadi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.