Native Bible

2 Samuel 13:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”

2 Samuel 13:24 in English

2 Samuel 13:24 · Berean Standard Bible

And he went to the king and said, “Your servant has just hired shearers. Will the king and his servants please come with me?”

Context

22Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú, nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. 23Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.” 25Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un. 26Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.