2 Samuẹli 13:25
2 Samuel 13:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.
2 Samuel 13:25 in English
2 Samuel 13:25 · Berean Standard Bible
“No, my son,” the king replied, “we should not all go, or we would be a burden to you.” Although Absalom urged him, he was not willing to go, but gave him his blessing.
Context
23Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.” 25Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un. 26Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”
Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” 27Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.