Native Bible

2 Samuel 11:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joabu sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dafidi.

2 Samuel 11:18 in English

2 Samuel 11:18 · Berean Standard Bible

Joab sent to David a full account of the battle

Context

16Ó sì ṣe nígbà tí Joabu ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Uriah sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀. 17Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Joabu jà, díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú. 18Joabu sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dafidi. 19Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí ìwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba. 20Bí ó bá ṣe pé, ìbínú ọba bá ru, ti òun sì wí fún ọ pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odi wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.