2 Samuẹli 11:17
2 Samuel 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Joabu jà, díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.
2 Samuel 11:17 in English
2 Samuel 11:17 · Berean Standard Bible
And when the men of the city came out and fought against Joab, some of David’s servants fell, and Uriah the Hittite also died.
Context
15Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Uriah síwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fàsẹ́yìn, kí wọn lè kọlù ú, kí ó sì kú.” 16Ó sì ṣe nígbà tí Joabu ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Uriah sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀. 17Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Joabu jà, díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú. 18Joabu sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dafidi. 19Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí ìwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.