2 Peteru 3:9
2 Peter 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.
2 Peter 3:9 in English
2 Peter 3:9 · Berean Standard Bible
The Lord is not slow in keeping His promise as some understand slowness, but is patient with you, not wanting anyone to perish but everyone to come to repentance.
Context
7Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run. 8Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bí ọjọ́ kan. 9Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà. 10Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú. 11Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.