Native Bible

2 Peter 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.

2 Peter 3:7 in English

2 Peter 3:7 · Berean Standard Bible

And by that same word, the present heavens and earth are reserved for fire, being kept for the day of judgment and destruction of ungodly men.

Context

5Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi. 6Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé. 7Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run. 8Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bí ọjọ́ kan. 9Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.