2 Peteru 3:8
2 Peter 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bí ọjọ́ kan.
2 Peter 3:8 in English
2 Peter 3:8 · Berean Standard Bible
Beloved, do not let this one thing escape your notice: With the Lord a day is like a thousand years, and a thousand years are like a day.*
Context
6Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé. 7Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run. 8Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bí ọjọ́ kan. 9Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà. 10Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.