Native Bible

2 Peter 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀.

2 Peter 3:14 in English

2 Peter 3:14 · Berean Standard Bible

Therefore, beloved, as you anticipate these things, make every effort to be found at peace—spotless and blameless in His sight.*

Context

12Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé. 14Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀. 15Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. 16Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.