Native Bible

2 Peter 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́.

2 Peter 3:12 in English

2 Peter 3:12 · Berean Standard Bible

as you anticipate and hasten the coming of the day of God, when the heavens will be destroyed by fire and the elements will melt in the heat.

Context

10Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú. 11Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run. 12Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé. 14Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.