Native Bible

2 Peter 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un.

2 Peter 3:15 in English

2 Peter 3:15 · Berean Standard Bible

Consider also that our Lord’s patience brings salvation, just as our beloved brother Paul also wrote you with the wisdom God gave him.

Context

13Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé. 14Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀. 15Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. 16Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn. 17Nítorí náà ẹ̀yin olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kíyèsára, kí a má ba à fi ìṣìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró ṣinṣin yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.