Native Bible

2 Kings 9:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli.

2 Kings 9:7 in English

2 Kings 9:7 · Berean Standard Bible

And you are to strike down the house of your master Ahab, so that I may avenge the blood of My servants the prophets and the blood of all the servants of the LORD shed by the hand of Jezebel.

Context

5Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí. “Sí ta ni nínú wa?” Jehu béèrè. Òun sì wí pé, “Sí ọ, balógun,” Ó dáhùn. 6Jehu dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jehu; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Israẹli. 7Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli. 8Gbogbo ilé Ahabu yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Ahabu gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Israẹli, ẹrú tàbí òmìnira. 9Èmi yóò ṣe ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati àti ilé Baaṣa ọmọ Ahijah.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.