Native Bible

2 Kings 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ilé Ahabu yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Ahabu gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Israẹli, ẹrú tàbí òmìnira.

2 Kings 9:8 in English

2 Kings 9:8 · Berean Standard Bible

The whole house of Ahab will perish, and I will cut off from Ahab every male,* both slave and free, in Israel.

Context

6Jehu dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jehu; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Israẹli. 7Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli. 8Gbogbo ilé Ahabu yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Ahabu gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Israẹli, ẹrú tàbí òmìnira. 9Èmi yóò ṣe ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati àti ilé Baaṣa ọmọ Ahijah. 10Fún Jesebeli, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jesreeli, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkú rẹ̀.’ ” Nígbà náà ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.