Native Bible

2 Kings 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí. “Sí ta ni nínú wa?” Jehu béèrè. Òun sì wí pé, “Sí ọ, balógun,” Ó dáhùn.

2 Kings 9:5 in English

2 Kings 9:5 · Berean Standard Bible

and when he arrived, the army commanders were sitting there. “I have a message for you, commander,” he said. “For which of us?” asked Jehu. “For you, commander,” he replied.

Context

3Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ Nígbà náà, ṣí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré, má ṣe jáfara!” 4Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti Gileadi. 5Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí. “Sí ta ni nínú wa?” Jehu béèrè. Òun sì wí pé, “Sí ọ, balógun,” Ó dáhùn. 6Jehu dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jehu; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Israẹli. 7Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.