2 Ọba 8:27
2 Kings 8:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Ahabu ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Ahabu.
2 Kings 8:27 in English
2 Kings 8:27 · Berean Standard Bible
And Ahaziah walked in the ways of the house of Ahab and did evil in the sight of the LORD like the house of Ahab, for he was a son-in-law of the house of Ahab.
Context
25Ní ọdún méjìlá Joramu ọmọkùnrin Ahabu ọba Israẹli, Ahasiah ọmọkùnrin Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀. 26Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní ọdún kan ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Ataliah, ọmọbìnrin Omri ọba Israẹli. 27Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Ahabu ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Ahabu. 28Ahasiah sì lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu lọ sí ogun lórí Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Siria ṣẹ́ Joramu lẹ́sẹ̀. 29Bẹ́ẹ̀ ni ọba Joramu padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí ará Siria ti jẹ ní yà lórí rẹ̀ ní Ramoti ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Aramu.
Nígbà náà Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jesreeli láti lọ wo Joramu ọmọ Ahabu nítorí tí ó fi ara pa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.