Native Bible

2 Kings 7:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin ọba.

2 Kings 7:11 in English

2 Kings 7:11 · Berean Standard Bible

The gatekeepers shouted the news, and it was reported to the king’s household.

Context

9Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Òní yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa sì pa á mọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjìyà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.” 10Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn asọ́bodè ìlú, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Siria kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.” 11Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin ọba. 12Ọba sì dìde ní òru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò sọ fún yín ohun tí àwọn ará Siria tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sá pamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtítọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè, àwa yóò sì wọ inú ìlú lọ.’ ” 13Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Èmí o bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí àwa kí ó mú márùn-ún nínú àwọn ẹṣin tí ó kù, nínú àwọn tí ó kù ní ìlú—kíyèsí i, wọ́n sá dàbí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Israẹli tí ó kù nínú rẹ̀, kíyèsí i, àní bí gbogbo ènìyàn Israẹli tí a run, sí jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.