2 Ọba 7:12
2 Kings 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì dìde ní òru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò sọ fún yín ohun tí àwọn ará Siria tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sá pamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtítọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè, àwa yóò sì wọ inú ìlú lọ.’ ”
2 Kings 7:12 in English
2 Kings 7:12 · Berean Standard Bible
So the king got up in the night and said to his servants, “Let me tell you what the Arameans have done to us. They know we are starving, so they have left the camp to hide in the field, thinking, ‘When they come out of the city, we will take them alive and enter the city.’”
Context
10Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn asọ́bodè ìlú, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Siria kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.” 11Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin ọba. 12Ọba sì dìde ní òru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò sọ fún yín ohun tí àwọn ará Siria tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sá pamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtítọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè, àwa yóò sì wọ inú ìlú lọ.’ ” 13Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Èmí o bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí àwa kí ó mú márùn-ún nínú àwọn ẹṣin tí ó kù, nínú àwọn tí ó kù ní ìlú—kíyèsí i, wọ́n sá dàbí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Israẹli tí ó kù nínú rẹ̀, kíyèsí i, àní bí gbogbo ènìyàn Israẹli tí a run, sí jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” 14Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan kẹ̀kẹ́ méjì pẹ̀lú ẹṣin wọn, ọba sì ránṣẹ́ tọ ogun àwọn ará Siria lẹ́yìn ó pàṣẹ fún àwọn awakọ̀ pé, “Ẹ lọ kí ẹ lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.