Native Bible

2 Kings 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí ọba Aramu wà ní ogun pẹ̀lú Israẹli ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbèrò, ó wí pé, “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.”

2 Kings 6:8 in English

2 Kings 6:8 · Berean Standard Bible

Now the king of Aram was at war against Israel. After consulting with his servants, he said, “My camp will be in such and such a place.”

Context

6Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Eliṣa gé igi kan ó sì jù ú síbẹ̀, ó sì mú irin náà fò lójú omi. 7Ó wí pé, “Gbé e jáde.” Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un. 8Nísinsin yìí ọba Aramu wà ní ogun pẹ̀lú Israẹli ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbèrò, ó wí pé, “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.” 9Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Israẹli pé, “Kíyèsi ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Aramu wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.” 10Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fihàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Eliṣa kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.