2 Ọba 6:7
2 Kings 6:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó wí pé, “Gbé e jáde.” Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un.
2 Kings 6:7 in English
2 Kings 6:7 · Berean Standard Bible
“Lift it out,” he said, and the man reached out his hand and took it.
Context
5Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kígbe sókè pé, “O! Olúwa mi, mo yá a ni!” 6Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Eliṣa gé igi kan ó sì jù ú síbẹ̀, ó sì mú irin náà fò lójú omi. 7Ó wí pé, “Gbé e jáde.” Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un. 8Nísinsin yìí ọba Aramu wà ní ogun pẹ̀lú Israẹli ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbèrò, ó wí pé, “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.” 9Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Israẹli pé, “Kíyèsi ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Aramu wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.