Native Bible

2 Kings 6:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fihàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Eliṣa kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀.

2 Kings 6:10 in English

2 Kings 6:10 · Berean Standard Bible

So the king of Israel sent word to the place the man of God had pointed out. Time and again * Elisha warned the king, so that he was on his guard in such places.

Context

8Nísinsin yìí ọba Aramu wà ní ogun pẹ̀lú Israẹli ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbèrò, ó wí pé, “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.” 9Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Israẹli pé, “Kíyèsi ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Aramu wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.” 10Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fihàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Eliṣa kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀. 11Èyí mú ọba Aramu bínú. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ìwọ kò ní sọ fún mi èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Israẹli?” 12Ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “Kò sí ọ̀kan nínú wa, olúwa ọba mi, ṣùgbọ́n Eliṣa, wòlíì tí ó wà ní Israẹli, sọ fún ọba Israẹli ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.