2 Ọba 6:25
2 Kings 6:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún.
2 Kings 6:25 in English
2 Kings 6:25 · Berean Standard Bible
So there was a great famine in Samaria. Indeed, they besieged the city so long that a donkey’s head sold for eighty shekels of silver,* and a quarter cab of dove’s dung * sold for five shekels of silver.*
Context
23Bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè àsè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Aramu dáwọ́ ìgbógunti ilẹ̀ Israẹli dúró. 24Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria. 25Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún. 26Gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sọkún sí i pé, “Ràn mí lọ́wọ́, olúwa ọba mi!” 27Ọba sì dá a lóhùn pé, “Bí Olúwa kò bá gbà ọ́, níbo ni èmi yóò gbé ti gbà ọ́? Láti inú ilẹ̀ ìpakà, tàbí láti inú ibi ìfúntí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.