Native Bible

2 Kings 6:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè àsè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Aramu dáwọ́ ìgbógunti ilẹ̀ Israẹli dúró.

2 Kings 6:23 in English

2 Kings 6:23 · Berean Standard Bible

So the king prepared a great feast for them, and after they had finished eating and drinking, he sent them away, and they returned to their master. And the Aramean raiders did not come into the land of Israel again.

Context

21Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?” 22“Má ṣe pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi síwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.” 23Bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè àsè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Aramu dáwọ́ ìgbógunti ilẹ̀ Israẹli dúró. 24Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria. 25Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.